6
1 Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn.
2 Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ọlá àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfààní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Asán ni èyí, ààrùn búburú gbá à ni.
3 Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rùn-ún ọmọ kí ó sì wà láààyè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, síbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láààyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo sọ wí pé ọlẹ̀ ọmọ tí a sin sàn jù ú lọ.
4 Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ fi ara pamọ́ sí.
5 Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìsinmi ju ti ọkùnrin náà lọ.
6 Kódà, bí ó wà láààyè fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun ìní rẹ̀. Kì í ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?
7 Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni
síbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí.
8 Kí ni àǹfààní tí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní lórí aṣiwèrè?
Kí ni èrè tálákà ènìyàn
nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tókù?
9 Ohun tí ojú rí sàn
ju ìfẹnuwákiri lọ.
Asán ni eléyìí pẹ̀lú
ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
10 Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ,
ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mí mọ̀;
kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì
pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jù ú lọ.
11 Ọ̀rọ̀ púpọ̀,
kì í ní ìtumọ̀
èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?
12 Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti asán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? Kò sí!