14
Ìwòsàn ń bẹ fún àwọn tó ronúpìwàdà
1 Yípadà ìwọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ!
2 Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́,
kí ẹ sì yípadà sí Olúwa.
Ẹ sọ fún un pé,
“Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá
kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá,
kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ
3 Asiria kò le gbà wá là;
a kò ní í gorí ẹṣin ogun.
A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé, ‘Àwọn ni òrìṣà wa’
sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe;
nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.”
4 “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn,
Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́,
nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
5 Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli,
wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì.
Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò.
6 Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà,
dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi.
Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni.
7 Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀.
Yóò rúwé bi ọkà.
Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà,
òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni.
8 Ìwọ Efraimu, kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà?
Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ.
Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù,
èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”
9 Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí.
Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn.
Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa
àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn,
ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.