52
+Jí, jí, ìwọ Sioni,
wọ ara rẹ ní agbára.
Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,
ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì.
Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́
kì yóò wọ inú rẹ mọ́.
Gbọn eruku rẹ kúrò;
dìde sókè, kí o sì gúnwà, ìwọ Jerusalẹmu.
Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,
ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí,
“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,
láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.
“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀
lọ sí Ejibiti láti gbé;
láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.
+“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí.
“Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,
àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”
ni Olúwa wí.
“Àti ní ọjọọjọ́
orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo.
Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;
nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀
pé, Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”
 
+Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè
ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá,
tí wọ́n kéde àlàáfíà,
tí ó mú ìyìnrere wá,
tí ó kéde ìgbàlà,
tí ó sọ fún Sioni pé,
“Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”
Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè
wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀.
Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni,
wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.
Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀,
ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu,
nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú,
ó sì ti ra Jerusalẹmu padà.
10 +Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀
ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí
ìgbàlà Ọlọ́run wa.
 
11 +Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín yìí!
Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan!
Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́,
ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.
12 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò
tàbí kí ẹ sáré lọ;
nítorí Olúwa ni yóò síwájú yín lọ,
Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.
Ìpọ́njú àti ògo ìránṣẹ́ náà
13 Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n;
òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbéga
a ó sì gbé e lékè gidigidi.
14 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un—
ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́.
15 +Bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀-èdè ká,
àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítorí rẹ̀.
Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i,
àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.
 
+ 52:1 If 21.27. + 52:5 Ro 2.24. + 52:7 Ap 10.36; Ro 10.15; Ef 6.15. + 52:10 Lk 2.30; 3.6. + 52:11 2Kọ 6.17. + 52:15 Ro 15.21.