17
1 “Ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a fi kálámù irin kọ,
èyí tí a fi ṣóńṣó òkúta adamante gbẹ́ ẹ,
sórí wàláà oókan àyà wọn,
àti sórí ìwo pẹpẹ yín.
2 Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ
àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ
àti àwọn òkè gíga.
3 Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀
àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ
pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó
pọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín.
4 Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yin
yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù.
Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrú
ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀,
nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi,
èyí tí yóò sì wà títí ayé.”
5 Báyìí ni Olúwa wí:
“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,
tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,
àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.
6 Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,
kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,
yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,
ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.
7 “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin
náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi
Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.
8 Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò
tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò
kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,
gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù
kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá
bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”
9 Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ,
ó kọjá ohun tí a lè wòsàn.
Ta ni èyí lè yé?
10 “Èmi Olúwa ń wo ọkàn
àti èrò inú ọmọ ènìyàn,
láti san èrè iṣẹ́ rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,
àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”
11 Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé
ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo.
Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀,
àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.
12 Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀
ní ibi ilé mímọ́ wa.
13 Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli;
gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì.
Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ
ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru,
nítorí wọ́n ti kọ Olúwa,
orísun omi ìyè sílẹ̀.
14 Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn,
gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà,
nítorí ìwọ ni ìyìn mi.
15 Wọ́n sọ fún mi wí pé:
“Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà?
Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.”
Ni Olúwa wí.
16 Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ,
ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.
17 Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi,
ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú.
18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,
ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú,
jẹ́ kí wọn kí ó dààmú.
Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn,
fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.
Pípa ọjọ́ ìsinmi mọ́
19 Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu.
20 Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí.
21 Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu.
22 Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.”
23 Síbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí.
24 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà.
25 Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé.
26 Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Juda àti ní agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Benjamini, láti pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti láti òkè, àti láti gúúsù wá, wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, àti ọrẹ ẹran, àti tùràrí, àti àwọn tó mú ìyìn wá sí ilé Olúwa.
27 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”