34
Ààlà ti Kenaani
1 Olúwa sọ fún Mose pé,
2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Tí ẹ bá wọ Kenaani, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí:
3 “ ‘Ìhà gúúsù yín yóò bọ́ sí ara aginjù Sini lẹ́bàá Edomu, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà gúúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,
4 kọjá lọ sí gúúsù Akrabbimu, tẹ̀síwájú lọ si Sini, kó bọ́ si gúúsù Kadeṣi-Barnea, kí o sì dé Hasari-Addari, kí o sì kọjá sí Asmoni.
5 Kí òpin ilẹ̀ rẹ̀ kí ó sì yíká láti Asmoni lọ dé odò Ejibiti, Òkun Ńlá ni yóò sì jẹ òpin rẹ.
6 Ìhà ìwọ̀-oòrùn yín yóò jẹ́ òpin lórí Òkun Ńlá. Èyí yóò jẹ́ ààlà yín lórí ìhà ìwọ̀-oòrùn.
7 Fún ààlà ìhà àríwá, fa ìlà láti Òkun Ńlá lọ sí orí òkè Hori,
8 àti láti orí òkè Hori sí Lebo-Hamati. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sedadi,
9 tẹ̀síwájú lọ sí Sifroni, kí o sì fò pín si ní Hasari-Enani, èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.
10 Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ tiyín ní ìhà ìlà-oòrùn láti Hasari-Enani lọ dé Ṣefamu.
11 Ààlà náà yóò ti Ṣefamu sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ribla ní ìhà ìlà-oòrùn Aini, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kinnereti ní ìhà ìlà-oòrùn.
12 Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jordani, yóò sì dópin nínú Òkun Iyọ̀.
“ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”
13 Mose pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti pàṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án, àti ààbọ̀.
14 Nítorí ará ilẹ̀ ẹ̀yà ti Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Manase ti gba ogún tiwọn.
15 Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún tiwọn ní ìhà ìhín Jordani létí i Jeriko, ní ìhà ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ Jordani.”
16 Olúwa sọ fún Mose pé,
17 “Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún: Eleasari àlùfáà àti Joṣua ọmọ Nuni.
18 Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà.
19 “Èyí ni orúkọ wọn:
“Kalebu ọmọ Jefunne, láti ẹ̀yà Juda;
20 Ṣemueli ọmọ Ammihudu, láti ẹ̀yà Simeoni;
21 Elidadi ọmọ Kisloni, láti ẹ̀yà Benjamini;
22 Bukki ọmọ Jogli, láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dani;
23 Hannieli ọmọ Efodu, láti ẹ̀yà Manase, olórí àwọn ọmọ Josẹfu,
24 Kemueli ọmọ Ṣiftani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ, Efraimu, ọmọ Josẹfu;
25 Elisafani ọmọ Parnaki, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Sebuluni;
26 Paltieli ọmọ Assani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Isakari;
27 Ahihudu ọmọ Ṣelomi, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Aṣeri;
28 Pedaheli ọmọ Ammihudu, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Naftali.”
29 Èyí ni àwọn ẹni tí Olúwa yàn láti pín ogún náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani.