Àwọn òwe mìíràn ti Solomoni
25
1 Wọ̀nyí ni àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa, tí àwọn ọkùnrin Hesekiah ọba Juda dà kọ.
2 Ògo Ọlọ́run ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́;
láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.
3 Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jì
bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.
4 Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà
ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà.
5 Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba
a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo.
6 Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba,
má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrín àwọn ènìyàn pàtàkì,
7 ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síyìn-ín,”
ju wí pé kí ó dójútì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.
8 Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí
má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn
bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?
9 Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ,
má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,
10 àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́
orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.
11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ
ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.
12 Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára
ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.
13 Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè
ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an
ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.
14 Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò
ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.
15 Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà
ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.
16 Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba
bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.
17 Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo
tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.
18 Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú
ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.
19 Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹsẹ̀ tí ó rọ
ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdààmú.
20 Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú,
tàbí, bí ọtí kíkan tí a dà sí ojú ọgbẹ́,
ní ẹni tí ń kọ orin fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́.
21 Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ;
bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.
22 Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí
Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.
23 Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá,
bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.
24 Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé
ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.
25 Bí omi tútù sí ọkàn tí ń ṣe àárẹ̀
ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.
26 Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kànga tí omi rẹ̀ bàjẹ́
ni olódodo tí ó fi ààyè gba ènìyàn búburú.
27 Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù,
bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́n ni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.
28 Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀
ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.