Saamu 110
Ti Dafidi. Saamu.
+Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,
 
“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”
 
Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀
láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá
ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,
láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.
 
+Olúwa ti búra,
kò sì í yí ọkàn padà pé,
“Ìwọ ni àlùfáà,
ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”
 
Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni
yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,
yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;
yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:
nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.
+ Saamu 110:1 Mt 22.44; 26.64; Mk 12.36; 14.62; 16.19; Lk 20.42-43; 22.69; Ap 2.34; 1Kọ 15.25; Ef 1.20; Kl 3.1; Hb 1.3,13; 10.12-13; 12.2. + Saamu 110:4 Hb 5.6,10; 6.20; 7.11,15,21.