Saamu 130
Orin fún ìgòkè.
Láti inú ibú wá ni
èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
Olúwa, gbóhùn mi,
jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
 
+Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
Olúwa, tá ni ìbá dúró.
Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,
kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.
 
Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,
àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí.
Ọkàn mi dúró de Olúwa,
ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,
àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
 
Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:
nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,
àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè
kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
+ Saamu 130:3 Sm 143.2; Ro 3.20; Ga 2.16.