Saamu 16
Miktamu ti Dafidi.
Pa mí mọ́, Ọlọ́run,
nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.
 
Mo sọ fún Olúwa, “Ìwọ ni Olúwa mi,
lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”
Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,
àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.
Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.
 
Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,
ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;
nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;
ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
+Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo.
Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.
 
Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;
ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
10  +nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,
tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;
Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,
pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
+ Saamu 16:8 Ap 2.25-28,31. + Saamu 16:10 Ap 13.35.