Saamu 30
Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.
Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
ìwọ sì ti wò mí sàn.
Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.
 
Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
 
Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
“a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
àyà sì fò mí.
 
Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
“Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”
 
11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.