Saamu 35
Ti Dafidi.
1 Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí;
kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!
2 Di asà àti àpáta mú,
kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!
3 Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ
kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi.
Sọ fún ọkàn mi pé,
“Èmi ni ìgbàlà rẹ.”
4 Kí wọn kí ó dààmú,
kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú;
kí a sì mú wọn padà,
kí a sì dààmú àwọn tí ń gbèrò ìpalára mi.
5 Jẹ́ kí wọn dàbí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́,
kí angẹli Olúwa kí ó máa lé wọn kiri.
6 Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́,
kí angẹli Olúwa kí ó máa lépa wọn!
7 Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi,
ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.
8 Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì.
Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀;
kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.
9 Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa,
àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀.
10 Gbogbo egungun mi yóò wí pé,
“Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa?
O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ,
tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”
11 Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde;
wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀.
12 Wọ́n fi búburú san ìre fún mi;
láti sọ ọkàn mi di òfo.
13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀;
mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú.
Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;
14 èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀
bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni.
Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́
bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.
15 Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ;
wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀.
Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.
16 Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ
wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.
17 Yóò ti pẹ́ tó Olúwa, tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ?
Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn,
àní ẹ̀mí ì mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún.
18 Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá;
èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.
19 Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi
kí ó yọ̀ lórí ì mi;
bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi
ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.
20 Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,
ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.
21 Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà!
Ojú wa sì ti rí i.”
22 Ìwọ́ ti rí i Olúwa; má ṣe dákẹ́!
Olúwa má ṣe jìnnà sí mi!
23 Dìde! ru ara rẹ̀ sókè fún ààbò mi,
àti sí ọ̀ràn mi, Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!
24 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ,
kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi!
25 Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!”
Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.”
26 Kí ojú kí ó tì wọ́n,
kí wọn kí ó sì dààmú pọ̀,
àní àwọn tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi
kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi.
27 Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi
fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú;
kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni Olúwa,
sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”
28 Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,
àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.