Saamu 44
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili.
1 À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run;
àwọn baba wa tí sọ fún wa
ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,
ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
2 Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde,
Ìwọ sì gbin àwọn baba wa;
ìwọ run àwọn ènìyàn náà
Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
3 Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà,
bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ;
àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.
4 Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,
ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
5 Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú;
nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀,
6 èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi,
idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
7 ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,
ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
8 Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,
àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé.
Sela.
9 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá,
Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.
10 Ìwọ ti bá wa jà,
ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,
àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa,
wọ́n sì fi ipá gba oko wa.
11 Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn,
Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.
12 Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré,
Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.
13 Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,
ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
14 Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
15 Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,
ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
16 nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.
17 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,
síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ
bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.
18 Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;
bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá,
ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú,
tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.
20 Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa
tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
21 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀,
níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?
22 Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́
a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.
23 Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?
Dìde fúnra rẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
24 Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́
tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?
25 Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku;
ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
26 Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́;
rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.