ÌWÉ KẸRIN
90
Saamu 90–106
Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run.
1 Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
2 Kí a tó bí àwọn òkè ńlá
àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,
láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
3 Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,
wí pé, “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
4 Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bá kọjá lójú rẹ,
bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
5 Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;
wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
6 Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun
ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.
7 A pa wá run nípa ìbínú rẹ
nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
8 Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,
àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ.
9 Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;
àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
bi ó sì ṣe pé nípa agbára
tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
àwa a sì fò lọ.
11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.
13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.
17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa,
bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.