Saamu 95
1 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa,
ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò
orin àti ìyìn.
3 Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,
ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
4 Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,
ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
5 Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a
àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,
ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú
Olúwa ẹni tí ó dá wa,
7 nítorí òun ni Ọlọ́run wa,
àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,
àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.
Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 “Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
9 nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò
tí wọn wádìí mi,
tí wọn sì rí iṣẹ́ mi.
10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;
mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ
wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi,
‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”