8
Ìtàn Ìdílé láti Ọ̀dọ̀ Baba Ńlá ti Saulu ará Benjamini
1 Benjamini jẹ́ baba:
Bela àkọ́bí rẹ̀,
Aṣbeli ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Ahara ẹ̀ẹ̀kẹ́ta,
2 Noha ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Rafa ẹ̀karùnún.
3 Àwọn ọmọ Bela ni,
Adari, Gera, Abihudi,
4 Abiṣua, Naamani, Ahoa,
5 Gera, Ṣefufani àti Huramu.
6 Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Ehudu, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Geba tí a sì lé kúrò lọ sí Manahati:
7 Naamani Ahijah àti Gera, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Ussa àti Ahihudu.
8 A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣaharaimu ní Moabu lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, Huṣimu àti Baara.
9 Nípasẹ̀ ìyàwó rẹ̀ Hodeṣi ó ní Jobabu Sibia, Meṣa, Malkamu,
10 Jeusi, Sakia àti Mirma. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, olórí àwọn ìdílé.
11 Nípasẹ̀ Huṣimu ó ní Abitubu àti Elipali.
12 Àwọn ọmọ Elipali:
Eberi, Miṣamu, Ṣemedu (ẹni tí ó kọ́ Ono àti Lodi pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká rẹ̀.)
13 Pẹ̀lú Beriah àti Ṣema, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Aijaloni àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gati kúrò.
14 Ahio, Ṣasaki, Jeremoti,
15 Sebadiah, Aradi, Ederi
16 Mikaeli, Iṣifa àti Joha jẹ́ àwọn ọmọ Beriah.
17 Sebadiah, Meṣullamu, Hiski, Heberi
18 Iṣimerai, Isiliahi àti Jobabu jẹ́ àwọn ọmọ Elipali.
19 Jakimu, Sikri, Sabdi,
20 Elienai, Siletai, Elieli,
21 Adaiah, Beraiah àti Ṣimrati jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣimei.
22 Iṣipani Eberi, Elieli,
23 Abdoni, Sikri, Hanani,
24 Hananiah, Elamu, Anitotijah,
25 Ifediah àti Penueli jẹ́ àwọn ọmọ Ṣasaki.
26 Ṣamṣerai, Ṣeharaiah, Ataliah
27 Jareṣiah, Elijah àti Sikri jẹ́ àwọn ọmọ Jerohamu.
28 Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìran wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.
29 Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni.
Ìyàwó o rẹ̀ a má jẹ́ Maaka,
30 àkọ́bí rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abdoni wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu,
31 Gedori Ahio, Sekeri
32 pẹ̀lú Mikiloti, tí ó jẹ́ baba Ṣimea. Wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.
33 Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba Saulu àti Saulu baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.
34 Ọmọ Jonatani:
Meribu-Baali tí ó jẹ́ baba Mika.
35 Àwọn ọmọ Mika:
Pitoni, Meleki, Tarea, àti Ahasi.
36 Ahasi jẹ́ baba a Jeheada, Jeheada jẹ́ baba a Alemeti, Asmafeti àti Simri, Simri sì jẹ́ baba Mosa.
37 Mosa jẹ́ baba Binea; Rafa sì jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.
38 Aseli ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:
Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli, Ṣeariah, Obadiah àti Hanani. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.
39 Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Eseki:
Ulamu àkọ́bí rẹ̀, Jeuṣi ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Elifeleti ẹ̀ẹ̀kẹ́ta.
40 Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin áàdọ́jọ ní gbogbo rẹ̀.
Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Benjamini.