21
Àsọtẹ́lẹ̀ tó lòdì sí Babeli
1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan aginjù lẹ́bàá Òkun.
Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní gúúsù,
akógunjàlú kan wá láti aginjù,
láti ilẹ̀ ìpayà.
2 Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fihàn mí
ọlọ̀tẹ̀ ti tu àṣírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù.
Elamu kojú ìjà! Media ti tẹ̀gùn!
Èmi yóò mú gbogbo ìpayínkeke dópin,
ni ó búra.
3 Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí,
ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti
obìnrin tí ń rọbí,
mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́,
ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí.
4 Ọkàn mí dàrú,
ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi,
ìmọ́lẹ̀ tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí
ti wá di ìpayà fún mi.
5 Wọ́n tẹ́ tábìlì,
wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká,
wọ́n jẹ, wọ́n mu!
Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé,
ẹ fi òróró kún asà yín!
6 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
“Lọ, kí o bojúwòde
kí o sì wá sọ ohun tí ó rí.
7 Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin,
àwọn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
tàbí àwọn tí ó gun ìbákasẹ,
jẹ́ kí ó múra sílẹ̀,
àní ìmúra gidigidi.”
8 Òun sì kígbe pé, kìnnìún kan,
“Láti ọjọ́ dé ọjọ́, olúwa mi, mo dúró lórí ilé ìṣọ́ ní ọ̀sán,
a sì fi mí ìṣọ́ mi ní gbogbo òru.
9 Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀ wá yìí nínú kẹ̀kẹ́ ogun
àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin.
Ó sì mú ìdáhùn padà wá:
‘Babeli ti ṣubú, ó ti ṣubú!
Gbogbo àwọn ère òrìṣà rẹ̀
ló fọ́nká sórí ilẹ̀!’ ”
10 Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gún mọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà,
mo sọ ohun tí mo ti gbọ́
láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Israẹli.
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Edomu
11 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Dumahi.
Ẹnìkan ké sí mi láti Seiri wá,
“Alóre, kí ló kù nínú òru náà?”
12 Alóre náà dáhùn wí pé,
“Òwúrọ̀ súnmọ́ tòsí, àti òru náà pẹ̀lú.
Bí ìwọ yóò bá béèrè, béèrè;
kí o sì tún padà wá.”
Àsọtẹ́lẹ̀ tó lòdì sí Arabia
13 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Arabia.
Ẹ̀yin ẹgbẹ́ èrò ti Dedani,
tí ó pàgọ́ sínú igbó Arabia,
14 gbé omi wá fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ;
ẹ̀yin tí ó ń gbé Tema,
gbé oúnjẹ wá fún àwọn ìsáǹsá.
15 Wọ́n sá kúrò lọ́wọ́ idà,
kúrò lọ́wọ́ idà tí a fàyọ,
kúrò lọ́wọ́ ọrun tí a fàyọ
àti kúrò nínú ìgbóná ogun.
16 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Láàrín ọdún kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ọgbà, í ti í kà á, gbogbo ògo ìlú Kedari yóò wá sí òpin.
17 Àwọn tafàtafà tí ó sálà, àwọn jagunjagun ìlú Kedari kò ní tó nǹkan.” Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ni ó ti sọ̀rọ̀.