22
Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Jerusalẹmu
1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ìran.
Kí ni ó ń dààmú yín báyìí,
tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ?
2 Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò,
ìwọ ìlú àìtòrò òun rògbòdìyàn
a kò fi idà pa àwọn òkú rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú ní ojú ogun.
3 Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ;
a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà.
Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀,
lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wà
lọ́nà jíjìn réré.
4 Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi:
jẹ́ kí n sọkún kíkorò.
Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínú
nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.”
5 Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan
tí rúkèrúdò àti rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀
ní àfonífojì ìmọ̀,
ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀
àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.
6 Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́,
pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,
Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta.
7 Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,
àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú.
8 Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò.
Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náà
sí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù.
9 Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi
ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀,
ìwọ ti tọ́jú omi
sínú adágún ti ìsàlẹ̀.
10 Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu
ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára.
11 Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjì
fún omi inú adágún àtijọ́,
ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀
tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ó
gbèrò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.
12 Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
pè ọ́ ní ọjọ́ náà
láti sọkún kí o sì pohùnréré,
kí o tu irun rẹ dànù kí o sì
da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.
13 Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà;
màlúù pípa àti àgùntàn pípa,
ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu!
Ẹ̀yin wí pé, “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu,
nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”
14 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
15 Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,
fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.
16 Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé
ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ
láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí,
tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga
tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?
17 “Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí
kí ó sì jù ọ́ nù, ìwọ ọkùnrin alágbára.
18 Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì
yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan.
Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí
àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà—
ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!
19 Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ,
a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.
20 “Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah.
21 Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda.
22 Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí.
23 Èmi yóò sì kàn mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní ààyè e rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀.
24 Gbogbo ògo ìdílé rẹ̀ ni wọn yóò sì fi kọ ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀, gbogbo ohun èlò ife, títí dé orí ago ọtí.
25 “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní ààyè e rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lórí i rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” Olúwa ni ó ti sọ ọ́.